4 Dafidi si ran amí jade, o si mọ̀ nitõtọ pe Saulu mbọ̀.
5 Dafidi si dide, o si wá si ibi ti Saulu pagọ si: Dafidi si ri ibi ti Saulu gbe dubulẹ si, ati Abneri ọmọ Neri, olori ogun rẹ̀: Saulu si dubulẹ larin awọn kẹ̀kẹ́, awọn enia na si pagọ wọn yi i ka.
6 Dafidi si dahun, o si wi fun Ahimeleki ọkan ninu awọn ọmọ Heti, ati fun Abiṣai ọmọ Seruia arákùnrin Joabu, pe, Tani o ba mi sọkalẹ lọ sọdọ Saulu ni ibudo? Abiṣai si wipe, emi o ba ọ sọkalẹ lọ.
7 Bẹ̃ni Dafidi ati Abiṣai si tọ awọn enia na wá li oru: si wõ, Saulu dubulẹ o si nsun larin kẹkẹ, a si fi ọ̀kọ rẹ̀ gunlẹ ni ibi timtim rẹ̀: Abneri ati awọn enia na si dubulẹ yi i ka.
8 Abiṣai si wi fun Dafidi pe, Ọlọrun ti fi ọta rẹ le ọ lọwọ loni: njẹ, emi bẹ ọ, sa jẹ ki emi ki o fi ọ̀kọ gun u mọlẹ lẹ̃kan, emi ki yio gun u lẹ̃meji.
9 Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Máṣe pa a: nitoripe tani le nawọ́ rẹ̀ si ẹni-ami-ororo Oluwa ki o si wà laijẹbi?
10 Dafidi si wipe, bi Oluwa ti mbẹ Oluwa yio pa a, tabi ọjọ rẹ̀ yio si pe ti yio kú, tabi on o sọkalẹ lọ si ibi ijà, a si ṣegbe nibẹ.