9 Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Máṣe pa a: nitoripe tani le nawọ́ rẹ̀ si ẹni-ami-ororo Oluwa ki o si wà laijẹbi?
10 Dafidi si wipe, bi Oluwa ti mbẹ Oluwa yio pa a, tabi ọjọ rẹ̀ yio si pe ti yio kú, tabi on o sọkalẹ lọ si ibi ijà, a si ṣegbe nibẹ.
11 Oluwa má jẹ ki emi nà ọwọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa: njẹ, emi bẹ ọ, mu ọ̀kọ na ti mbẹ nibi timtim rẹ̀, ati igo omi ki a si ma lọ.
12 Dafidi si mu ọ̀kọ na, ati igo omi na kuro nibi timtim Saulu: nwọn si ba ti wọn lọ, kò si si ẹnikan ti o ri i, tabi ti o mọ̀; kò si si ẹnikan ti o ji; gbogbo wọn si sùn; nitoripe orun àjika lati ọdọ Oluwa wá ti ṣubu lù wọn.
13 Dafidi si rekọja si iha keji, o si duro lori oke kan ti o jina rere; afo nla kan si wà lagbedemeji wọn:
14 Dafidi si kọ si awọn enia na, ati si Abneri ọmọ Neri wipe, Iwọ kò dahun, Abneri? Nigbana ni Abneri si dahun wipe, Iwọ tani npe ọba?
15 Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ.