1 DAFIDI si wi li ọkàn ara rẹ̀ pe, njẹ ni ijọ kan l'emi o ti ọwọ́ Saulu ṣegbe, ko si si ohun ti o yẹ mi jù ki emi ki o yara sa asala lọ si ilẹ awọn Filistini: yio su Saulu lati ma tun wá mi kiri ni gbogbo agbegbe Israeli: emi a si bọ li ọwọ́ rẹ̀.
2 Dafidi si dide, o si rekọja, on ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.
3 Dafidi si ba Akiṣi joko ni Gati, on, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, olukuluku wọn ti on ti ara ile rẹ̀; Dafidi pẹlu awọn aya rẹ̀ mejeji, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili ara Karmeli aya Nabali.
4 A si sọ fun Saulu pe, Dafidi sa lọ si Gati: on ko si tun wá a kiri mọ.