3 Samueli sì ti kú, gbogbo Israeli si sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ni Rama ni ilu rẹ̀. Saulu si ti mu awọn abokusọ̀rọ-ọkunrin, ati awọn abokusọ̀rọ-obinrin kuro ni ilẹ na.
4 Awọn Filistini si ko ara wọn jọ, nwọn wá, nwọn si do si Ṣunemu: Saulu si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si tẹdo ni Gilboa.
5 Nigbati Saulu si ri ogun awọn Filistini na, on si bẹ̀ru, aiya rẹ̀ si warìri gidigidi.
6 Nigbati Saulu si bere lọdọ Oluwa, Oluwa kò da a lohùn nipa alá, nipa Urimu tabi nipa awọn woli.
7 Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ.
8 Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi.
9 Obinrin na si da a lohùn pe, Wõ, iwọ sa mọ̀ ohun ti Saulu ṣe, bi on ti ke awọn abokusọ̀rọ obinrin, ati awọn abokusọ̀rọ ọkunrin kuro ni ilẹ na; njẹ eha ṣe ti iwọ dẹkùn fun ẹmi mi, lati mu ki nwọn pa mi?