1 AWỌN Filistini si ko gbogbo ogun wọn jọ si Afeki: Israeli si do ni ibi isun omi ti o wà ni Jesreeli.
2 Awọn ijoye Filistini si kọja li ọrọrun ati li ẹgbẹgbẹrun; Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pẹlu Akiṣi si kẹhin.
3 Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi.
4 Awọn ijoye Filistini si binu si i; awọn ijoye Filistini si wi fun u pe, jẹ ki ọkunrin yi pada ki o si lọ si ipò rẹ̀ ti o fi fun u, ki o má si jẹ ki o ba wa sọkalẹ lọ si ogun, ki o má ba jasi ọta fun wa li ogun; Kini on o fi ba oluwa rẹ̀ laja, ori awọn enia wọnyi kọ?
5 Ṣe eyi ni Dafidi ti nwọn tori rẹ̀ gberin ara wọn ninu ijo wipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbãrun tirẹ̀?