1 AWỌN Filistini si ko gbogbo ogun wọn jọ si Afeki: Israeli si do ni ibi isun omi ti o wà ni Jesreeli.
2 Awọn ijoye Filistini si kọja li ọrọrun ati li ẹgbẹgbẹrun; Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pẹlu Akiṣi si kẹhin.
3 Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi.
4 Awọn ijoye Filistini si binu si i; awọn ijoye Filistini si wi fun u pe, jẹ ki ọkunrin yi pada ki o si lọ si ipò rẹ̀ ti o fi fun u, ki o má si jẹ ki o ba wa sọkalẹ lọ si ogun, ki o má ba jasi ọta fun wa li ogun; Kini on o fi ba oluwa rẹ̀ laja, ori awọn enia wọnyi kọ?
5 Ṣe eyi ni Dafidi ti nwọn tori rẹ̀ gberin ara wọn ninu ijo wipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbãrun tirẹ̀?
6 Akiṣi si pe Dafidi, o si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, iwọ jẹ olõtọ ati ẹni ìwa rere loju mi, ni alọ rẹ ati abọ̀ rẹ pẹlu mi li ogun; nitoripe emi ko iti ri buburu kan lọwọ rẹ lati ọjọ ti iwọ ti tọ̀ mi wá, titi o fi di oni yi: ṣugbọn loju awọn ijoye iwọ kò ṣe ẹni ti o tọ́.
7 Njẹ yipada ki o si ma lọ li alafia, ki iwọ ki o má ba ṣe ibanujẹ fun awọn Filistini.