18 Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.
19 Samueli ndagba, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀, kò si jẹ ki ọkan ninu ọ̀rọ rẹ̀ wọnni bọ́ silẹ.
20 Gbogbo Israeli lati Dani titi o fi de Beerṣeba mọ̀ pe a ti fi Samueli kalẹ ni woli fun Oluwa.
21 Oluwa si nfi ara hàn a ni Ṣilo: nitoriti Oluwa ti fi ara rẹ̀ han fun Samueli ni Ṣilo nipa ọ̀rọ Oluwa.