8 Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.
9 Bẹni Dafidi ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si lọ, nwọn si wá si ibi odo Besori, apakan si duro.
10 Ṣugbọn Dafidi ati irinwo ọmọkunrin lepa wọn: igba enia ti ãrẹ̀ mu, ti nwọn kò le kọja odò Besori si duro lẹhin.
11 Nwọn si ri ara Egipti kan li oko, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá, nwọn si fun u li onjẹ, o si jẹ; nwọn si fun u li omi mu;
12 Nwọn si bùn u li akara eso ọpọtọ ati ṣiri ajara gbigbẹ meji: nigbati o si jẹ ẹ tan, ẹmi rẹ̀ si sọji: nitoripe ko jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò si mu omi ni ijọ mẹta li ọsan, ati li oru.
13 Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan.
14 Awa si gbe ogun lọ siha gusu ti ara Keriti, ati si apa ti iṣe ti Juda, ati si iha gusu ti Kelebu; awa si kun Siklagi.