10 Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ si ile Aṣtaroti: nwọn si kàn okú rẹ̀ mọ odi Betṣani.
11 Nigbati awọn ara Jabeṣi-Gileadi si gbọ́ eyiti awọn Filistini ṣe si Saulu;
12 Gbogbo awọn ọkunrin alagbara si dide, nwọn si fi gbogbo oru na rìn, nwọn si gbe okú Saulu, ati okú awọn ọmọbibi rẹ̀ kuro lara odi Betṣani, nwọn si wá si Jabeṣi, nwọn si sun wọn nibẹ.
13 Nwọn si ko egungun wọn, nwọn si sin wọn li abẹ igi kan ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.