3 Ijà na si buru fun Saulu gidigidi, awọn tafàtafa si ta a li ọfà, o si fi ara pa pupọ li ọwọ́ awọn tafàtafa.
4 Saulu si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Fa ìda rẹ yọ, ki o si fi i gún mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má bà wá gún mi, ati ki wọn ki o má ba fi mi ṣe ẹlẹya. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ ko fẹ ṣe bẹ̃, nitoripe ẹrù ba a gidigidi. Saulu si mu idà na o si fi pa ara rẹ̀.
5 Nigbati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na si fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, o si kú pẹlu rẹ̀.
6 Saulu si kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ẹni ti o rù ihamọra rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀ li ọjọ kanna.
7 Nigbati awọn ọkunrin Israeli ti o wà li apa keji afonifoji na, ati awọn ẹniti o wà li apa keji Jordani, ri pe awọn ọkunrin Israeli sa, ati pe Saulu ati awọn ọmọbibi rẹ̀ si kú, nwọn si fi ilu silẹ, nwọn si sa; awọn Filistini si wá, nwọn si joko si ilu wọn.
8 O si ṣe, li ọjọ keji, nigbati awọn Filistini de lati bọ́ nkan ti mbẹ lara awọn ti o kú, nwọn si ri pe, Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta ṣubu li oke Gilboa,
9 Nwọn si ke ori rẹ̀, nwọn si bọ́ ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ lọ si ilẹ Filistini ka kiri, lati ma sọ ọ nigbangba ni ile oriṣa wọn, ati larin awọn enia.