5 Nigbati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na si fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, o si kú pẹlu rẹ̀.
6 Saulu si kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ẹni ti o rù ihamọra rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀ li ọjọ kanna.
7 Nigbati awọn ọkunrin Israeli ti o wà li apa keji afonifoji na, ati awọn ẹniti o wà li apa keji Jordani, ri pe awọn ọkunrin Israeli sa, ati pe Saulu ati awọn ọmọbibi rẹ̀ si kú, nwọn si fi ilu silẹ, nwọn si sa; awọn Filistini si wá, nwọn si joko si ilu wọn.
8 O si ṣe, li ọjọ keji, nigbati awọn Filistini de lati bọ́ nkan ti mbẹ lara awọn ti o kú, nwọn si ri pe, Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta ṣubu li oke Gilboa,
9 Nwọn si ke ori rẹ̀, nwọn si bọ́ ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ lọ si ilẹ Filistini ka kiri, lati ma sọ ọ nigbangba ni ile oriṣa wọn, ati larin awọn enia.
10 Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ si ile Aṣtaroti: nwọn si kàn okú rẹ̀ mọ odi Betṣani.
11 Nigbati awọn ara Jabeṣi-Gileadi si gbọ́ eyiti awọn Filistini ṣe si Saulu;