16 Ọkunrin na si wi fun Eli pe, Emi li ẹniti o ti ogun wá, loni ni mo sa ti ogun na wá; o si bi i pe, Eti ri, ọmọ mi?
17 Ẹniti o mu ihin wá si dahun o si wipe, Israeli sa niwaju awọn Filistini, iṣubu na si pọ ninu awọn enia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji, Hofni ati Finehasi si kú, nwọn si gbà apoti Ọlọrun.
18 O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun.
19 Aya ọmọ rẹ̀, obinrin Finehasi, loyun, o si sunmọ ọjọ ibi rẹ̀; nigbati o si gbọ́ ihìn pe a ti gbà apoti Ọlọrun, ati pe, baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ kú, o kunlẹ, o si bimọ, nitori obí tẹ̀ ẹ.
20 Lakoko ikú rẹ̀ awọn obinrin ti o duro tì i si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; nitoriti iwọ bi ọmọkunrin kan. Ko dahun, kò si kà a si.
21 On si pe ọmọ na ni Ikabodu, wipe, Kò si ogo fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun, ati nitori ti baba ọkọ rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀.
22 O si wipe, Ogo kò si fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun.