5 Nitorina awọn alufa Dagoni, ati gbogbo awọn ti ima wá si ile Dagoni, kò si tẹ oju ọ̀na Dagoni ni Aṣdodu titi di oni.
6 Ọwọ́ Oluwa si wuwo si ara Aṣdodu, o si pa wọn run, o si fi iyọdi pọn wọn loju, ani Aṣdodu ati agbegbe rẹ̀.
7 Nigbati awọn enia Aṣdodu ri pe bẹ̃ li o ri, nwọn si wi pe, Apoti Ọlọrun Israeli kì yio ba wa gbe: nitoripe ọwọ́ rẹ̀ wuwo si wa, ati si Dagoni ọlọrun wa.
8 Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ.
9 O si ṣe pe, lẹhin igbati nwọn gbe e lọ tan, ọwọ́ Oluwa si wà si ilu na pẹlu iparun nla, o si pọn awọn enia ilu na loju, ati ọmọde ati agbà, nwọn ni iyọdi.
10 Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa.
11 Bẹ̃ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pe gbogbo ijoye Filistini jọ, nwọn si wipe, Rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, ki ẹ si jẹ ki o tun pada lọ si ipò rẹ̀, ki o má ba pa wa, ati awọn enia wa: nitoriti ipaiya ikú ti wà ni gbogbo ilu na; ọwọ́ Ọlọrun si wuwo gidigidi ni ibẹ.