24 Alase na si gbe ejika na, ati eyi ti o wà lori rẹ̀, o si gbe e kalẹ niwaju Saulu. Samueli si wipe, Wo eyi ti a fi silẹ! fà a sọdọ rẹ, ki o si ma jẹ: nitoripe titi di isisiyi li ati pa a mọ fun ọ lati igbati mo ti wipe, emi ti pe awọn enia na. Bẹ̃ni Saulu si ba Samueli jẹun li ọjọ na.
25 Nigbati nwọn sọkalẹ lati ibi giga nì wá si ilu, Samueli si ba Saulu sọrọ lori orule.
26 Nwọn si dide ni kutukutu: o si ṣe, li afẹmọjumọ, Samueli si pe Saulu sori orule, wipe, Dide, emi o si ran ọ lọ. Saulu si dide, awọn mejeji sì jade, on ati Samueli, si gbangba.
27 Bi nwọn si ti nsọkalẹ lọ si ipẹkun ilu na, Samueli wi fun Saulu pe, Wi fun iranṣẹ ki o kọja si iwaju wa, (o si kọja) ṣugbọn ki iwọ ki o duro diẹ, ki emi ki o le fi ọ̀rọ Ọlọrun hàn ọ́.