5 Nigbana ni ọba Assiria gòke wá si gbogbo ilẹ na, o si gòke lọ si Samaria, o si dotì i li ọdun mẹta.
6 Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.
7 O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran.
8 Ti nwọn si nrìn ninu ilana awọn keferi, ti Oluwa ti le jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, ati ti awọn ọba Israeli, ti nwọn ti ṣe.
9 Awọn ọmọ Israeli si ṣe ohun ikọ̀kọ ti kò tọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kọ́ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.
10 Nwọn si gbé awọn ere kalẹ, nwọn si dá ere oriṣa si lori òke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo:
11 Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi ti Oluwa kó lọ niwaju wọn ti ṣe; nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu Oluwa soke.