3 O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe,
4 Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia:
5 Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe.
6 Fun awọn gbẹnagbẹna, ati fun awọn akọle, ati awọn ọ̀mọle, lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tún ile na ṣe.
7 Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ.
8 Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a.
9 Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa.