1 IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu.
2 Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀;
3 Juda si bí Faresi ati Sara ti Tamari; Faresi si bí Esromu; Esromu si bí Aramu;
4 Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni;
5 Salmoni si bí Boasi ti Rakabu; Boasi si bí Obedi ti Rutu; Obedi si bí Jesse;
6 Jesse si bí Dafidi ọba. Dafidi ọba si bí Solomoni lati ọdọ ẹniti o ti nṣe aya Uria;
7 Solomoni si bí Rehoboamu; Rehoboamu si bí Abia; Abia si bí Asa;
8 Asa si bí Jehosafati; Jehosafati si bí Joramu; Joramu si bí Osia;
9 Osia si bí Joatamu; Joatamu si bí Akasi; Akasi si bí Hesekiah;
10 Hesekiah si bí Manasse; Manasse si bí Amoni; Amoni si bí Josiah;
11 Josiah si bí Jekoniah ati awọn arakunrin rẹ̀, nigba ikolọ si Babiloni.
12 Lẹhin ikolọ si Babiloni ni Jekoniah bí Sealtieli; Sealtieli si bí Serubabeli;
13 Serubabeli si bí Abiudu; Abiudu si bí Eliakimu; Eliakimu si bí Asoru;
14 Asoru si bí Sadoku; Sadoku si bí Akimu; Akimu si bí Eliudu;
15 Eliudu si bí Eleasa; Eleasa si bí Matani; Matani si bí Jakọbu;
16 Jakọbu si bí Josefu ọkọ Maria, lati ọdọ ẹniti a bí Jesu, ti a npè ni Kristi.
17 Bẹ̃ni gbogbo iran lati Abrahamu wá de Dafidi jẹ iran mẹrinla; ati lati Dafidi wá de ikolọ si Babiloni jẹ iran mẹrinla; ati lati igba ikólọ si Babiloni de igba Kristi o jẹ iran mẹrinla.
18 Bi ibí Jesu Kristi ti ri niyi: li akokò ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josefu, ki nwọn to pade, a ri i, o lóyun lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.
19 Josefu ọkọ rẹ̀, ti iṣe olõtọ enia, ko si fẹ dojutì i ni gbangba, o fẹ ikọ̀ ọ silẹ ni ìkọkọ.
20 Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angẹli Oluwa yọ si i li oju alá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má fòiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ ni.
21 Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn.
22 Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe,
23 Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa.
24 Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ̀, o ṣe bi angẹli Oluwa ti wi fun u, o si mu aya rẹ̀ si ọdọ:
25 On ko si mọ̀ ọ titi o fi bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin: o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.