Mat 12 YCE

Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà ní Ọjọ́ Ìsinmi

1 LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ.

2 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi.

3 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀:

4 Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa?

5 Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi?

6 Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin.

7 Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi.

8 Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi.

Ọkunrin tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

9 Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn.

10 Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀.

11 O si wi fun wọn pe, ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke?

12 Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ? nitorina li o ṣe tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi.

13 Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ, on si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji.

Iranṣẹ Ọlọrun

14 Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.

Iranṣẹ Ọlọrun

15 Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada.

16 O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn:

17 Ki eyi ti a ti ẹnu wolĩ Isaiah wi ki o ba le ṣẹ, pe,

18 Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi.

19 On kì yio jà, kì yio si kigbe; bẹ̃li ẹnikẹni kì yio gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro.

20 Iyè fifọ́ ni on kì yio ṣẹ́, owu fitila ti nru ẹ̃fin nì on kì yio si pa, titi yio fi mu idajọ dé iṣẹgun.

21 Orukọ rẹ̀ li awọn keferi yio ma gbẹkẹle.

Jesu ati Beelisebulu

22 Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran.

23 Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi?

24 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu.

25 Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro.

26 Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yapa si ara rẹ̀; ijọba rẹ̀ yio ha ṣe le duro?

27 Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina ni nwọn o fi ma ṣe onidajọ nyin.

28 Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin.

29 Tabi ẹnikan yio ti ṣe wọ̀ ile alagbara lọ, ki o si kó o li ẹrù, bikoṣepe o kọ́ dè alagbara na? nigbana ni yio si kó o ni ile.

30 Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka.

31 Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia.

32 Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀.

Igi ati Èso Rẹ̀

33 Sọ igi di rere, eso rẹ̀ a si di rere; tabi sọ igi di buburu, eso rẹ̀ a si di buburu: nitori nipa eso li ã fi mọ igi.

34 Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ.

35 Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá.

36 Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.

37 Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi.

38 Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe ati Farisi dahùn wipe, Olukọni, awa nwá àmi lọdọ rẹ.

39 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Iran buburu ati iran panṣaga nwá àmi; kò si àmi ti a o fi fun u, bikoṣe àmi Jona wolĩ.

40 Nitori bi Jona ti gbé ọsán mẹta ati oru mẹta ninu ẹja; bẹ̃li Ọmọ-enia yio gbé ọsán mẹta on oru mẹta ni inu ilẹ.

41 Awọn ara Ninefe yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, nwọn, o si da a lẹbi: nitori nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Jona lọ mbẹ nihinyi.

42 Ọbabirin gusù yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, yio si da a lẹbi: nitori o ti ikangun aiye wá igbọ́ ọgbọ́n Solomoni; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.

Ẹ̀mí-Èṣù tún Pada sí Ilé Rẹ̀

43 Nigbati ẹmi aimọ́ kan ba jade kuro lara enia, a ma rìn kiri ni ibi gbigbẹ, a ma wá ibi isimi, kì si iri.

44 Nigbana ni o wipe, Emi o pada lọ si ile mi, nibiti mo gbé ti jade wá; nigbati o si de, o bá a, o ṣofo, a gbá a mọ́, a si ṣe e li ọṣọ.

45 Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu ara rẹ̀, ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn bọ si inu rẹ̀, nwọn si ngbé ibẹ̀; igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri fun iran buburu yi pẹlu.

Ìyá Jesu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

46 Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ.

47 Nigbana li ẹnikan wi fun u pe, Wo o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ba ọ sọ̀rọ.

48 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun ẹniti o sọ fun u pe, Tani iya mi? ati tani awọn arakunrin mi?

49 O si nà ọwọ́ rẹ̀ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Ẹ wò iya mi ati awọn arakunrin mi!

50 Nitori ẹnikẹni ti o ba nṣe ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28