Mat 23 YCE

Jesu Bá Àwọn Amòfin ati Àwọn Farisi Wí

1 NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,

2 Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose:

3 Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe.

4 Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na.

5 Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn.

6 Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu,

7 Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi.

8 Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin.

9 Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun.

10 Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi.

11 Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin.

12 Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga.

Jesu Dá Àwọn Amòfin ati Àwọn Farisi Lẹ́bi

13 Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle.

14 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin jẹ ile awọn opó run, ati nitori aṣehan, ẹ ngbadura gigun: nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọ̀ju.

15 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ.

16 Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese.

17 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́?

18 Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese.

19 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́?

20 Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀.

21 Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀.

22 Ẹniti o ba si fi ọrun bura, o fi itẹ́ Ọlọrun bura, ati ẹniti o joko lori rẹ̀.

23 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe.

24 Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì.

25 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia.

26 Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu.

27 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo.

28 Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu ẹ kún fun agabagebe ati ẹ̀ṣẹ.

Wọn Yóo Jèrè Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn

29 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin kọ́ ibojì awọn wolĩ, ẹnyin si ṣe isà okú awọn olododo li ọṣọ,

30 Ẹnyin si wipe, Awa iba wà li ọjọ awọn baba wa, awa kì ba li ọwọ́ ninu ẹ̀jẹ awọn wolĩ.

31 Njẹ ẹnyin li ẹlẹri fun ara nyin pe, ẹnyin li awọn ọmọ awọn ẹniti o pa awọn wolĩ.

32 Njẹ ẹnyin kuku kún òṣuwọn baba nyin de oke.

33 Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi?

34 Nitorina ẹ kiyesi i, Emi rán awọn wolĩ, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin ó si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu:

35 Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ.

36 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo nkan wọnyi ni yio wá sori iran yi.

Jesu Kẹ́dùn fún Jerusalẹmu

37 Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!

38 Sawò o, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro.

39 Mo si wi fun nyin, Ẹnyin kì yio ri mi mọ́ lati isisiyi lọ, titi ẹnyin o fi wipe, Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28