Mat 15 YCE

Àṣà Ìbílẹ̀ Àwọn Juu

1 NIGBANA li awọn akọwe ati awọn Farisi ti Jerusalemu tọ̀ Jesu wá, wipe,

2 Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ fi nrú ofin atọwọdọwọ awọn alàgba? nitoriti nwọn kì iwẹ̀ ọwọ́ wọn nigbati nwọn ba njẹun.

3 Ṣugbọn o dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin pẹlu nfi ofin atọwọdọwọ nyin rú ofin Ọlọrun?

4 Nitori Ọlọrun ṣòfin, wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ati ẹniti o ba sọrọ baba ati iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀.

5 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẹnikẹni ti o ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, Ẹbùn li ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi,

6 Ti ko si bọ̀wọ fun baba tabi iya rẹ̀, o bọ́. Bẹ̃li ẹnyin sọ ofin Ọlọrun di asan nipa ofin atọwọdọwọ nyin.

7 Ẹnyin agabagebe, otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti nyin, wipe,

8 Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.

9 Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ.

10 O si pè ijọ enia, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ki o si ye nyin;

11 Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́.

12 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ pe, awọn Farisi binu lẹhin igbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ yi?

13 O si dahùn, o wi fun wọn pe, Igikigi ti Baba mi ti mbẹ li ọrun kò ba gbìn, a o fà a tu kuro.

14 Ẹ jọwọ wọn si: afọju ti nfọ̀nahàn afọju ni nwọn. Bi afọju ba si nfọnahàn afọju, awọn mejeji ni yio ṣubu sinu ihò.

15 Nigbana ni Peteru dahùn o si wi fun u pe, Sọ itumọ owe yi fun wa.

16 Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ?

17 Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade?

18 Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́.

19 Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu;

20 Ohun wọnyi ni isọ enia di alaimọ́: ṣugbọn ki a jẹun li aiwẹwọ́ kò sọ enia di alaimọ́.

Igbagbọ Obinrin Ará Kenaani Kan

21 Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni.

22 Si wò o, obinrin kan ara Kenaani ti ẹkùn na wá, o si kigbe pè e, wipe, Oluwa, iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi; ọmọbinrin mi li ẹmi èṣu ndá lóró gidigidi.

23 Ṣugbọn kò si dá a lohùn ọrọ kan. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn bẹ̀ ẹ, wipe, Rán a lọ kuro, nitoriti o nkigbe tọ̀ wá lẹhin.

24 Ṣugbọn o dahùn wipe, A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israeli ti o nù.

25 Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ.

26 Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá.

27 O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ.

28 Nigbana ni Jesu dahùn o si wi fun u pe, Obinrin yi, igbagbọ́ nla ni tirẹ: ki o ri fun ọ gẹgẹ bi iwọ ti nfẹ. A si mu ọmọbinrin rẹ̀ larada ni wakati kanna.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

29 Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o wá si eti okun Galili, o gùn ori òke lọ, o si joko nibẹ̀.

30 Ọpọ enia si tọ̀ ọ wá ti awọn ti amukun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ awọn miran, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o si mu wọn larada:

31 Tobẹ̃, ti ẹnu yà ijọ enia na, nigbati nwọn ri ti odi nfọhùn, ti arọ ndi ọ̀tọtọ, ti amukun nrìn, ti afọju si nriran: nwọn si yìn Ọlọrun Israeli logo.

Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan

32 Jesu si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọdọ, o si wipe, Anu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn ko si li ohun ti nwọn o jẹ: emi kò si fẹ rán wọn lọ li ebi, ki ãrẹ̀ má bà mu wọn li ọ̀na.

33 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo li awa o ti ri akara to li aginjù, ti yio fi yó ọ̀pọ enia yi?

34 Jesu wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn wipe, Meje, pẹlu ẹja kekeke diẹ.

35 O si paṣẹ ki a mu ijọ enia joko ni ilẹ.

36 O si mu iṣu akara meje, ati ẹja na, o sure, o bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia.

37 Gbogbo nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n meje kún.

38 Awọn ti o jẹun to ẹgbaji ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde.

39 O si rán ijọ enia lọ; o si bọ́ sinu ọkọ̀, o lọ si ẹkùn Magdala.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28