Mat 9 YCE

Jesu Wo Arọ kan Sàn

1 O si bọ sinu ọkọ̀, o rekọja, o si wá si ilu on tikararẹ̀.

2 Si kiyesi i, nwọn gbé ọkunrin kan ti o li ẹ̀gba wá sọdọ rẹ̀, o dubulẹ lori akete; nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọkunrin, tújuka, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.

3 Si kiyesi i, awọn ọkan ninu awọn akọwe nwi ninu ara wọn pe, ọkunrin yi nsọrọ-odi.

4 Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin?

5 Ewo li o rọrun ju, lati wipe, A dari ẹṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, ki o si mã rìn?

6 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o si wi fun alarun ẹ̀gba na pe,) Dide, si gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.

7 O si dide, o si lọ ile rẹ̀.

8 Nigbati ijọ enia si ri i, ẹnu yà wọn, nwọn yìn Ọlọrun logo, ti o fi irú agbara bayi fun enia.

Jesu Pe Matiu

9 Bi Jesu si ti nrekọja lati ibẹ̀ lọ, o ri ọkunrin kan ti a npè ni Matiu joko ni bode; o sì wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin.

10 O si ṣe, bi Jesu ti joko tì onjẹ ninu ile, si kiyesi i, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá, nwọn si ba a joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

11 Nigbati awọn Farisi si ri i, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Olukọ nyin fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun pọ̀?

12 Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da.

13 Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

Ìbéèrè nípa Ààwẹ̀

14 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Johanu tọ̀ ọ wá wipe, Èṣe ti awa ati awọn Farisi fi ngbàwẹ nigbagbogbo, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?

15 Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ.

16 Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju.

17 Bẹ̃ni ko si ẹniti ifi waini titun sinu ogbologbo igo-awọ; bi a ba ṣe bẹ̃, igo-awọ yio bẹ́, waini a si tú jade, igo-awọ a si ṣegbe; ṣugbọn waini titun ni nwọn ifi sinu igo-awọ titun, awọn mejeji a si ṣe dede.

Ọmọdebinrin Ìjòyè kan ati Obinrin Onísun Ẹ̀jẹ̀

18 Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè.

19 Jesu dide, o si ba a lọ, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

20 Si kiyesi i, obinrin kan ti o ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, o wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀.

21 Nitori o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ kàn aṣọ rẹ̀, ara mi ó da.

22 Nigbati Jesu si yi ara rẹ̀ pada ti o ri i, o wipe, Ọmọbinrin, tújuka, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. A si mu obinrin na larada ni wakati kanna.

23 Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo.

24 O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà.

25 Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide.

26 Okikí si kàn ká gbogbo ilẹ nã.

Jesu La Àwọn Afọ́jú Meji Lójú

27 Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.

28 Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa.

29 Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin.

30 Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀.

31 Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká.

Jesu Wo Odi kan Sàn

32 Bi nwọn ti njade lọ, wò o, nwọn mu ọkunrin odi kan tọ̀ ọ wá, ti o li ẹmi èṣu.

33 Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli.

34 Ṣugbọn awọn Farisi wipe, agbara olori awọn ẹmi èṣu li o fi lé awọn ẹmi èṣu jade.

Jesu Aláàánú

35 Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwãsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.

36 Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti ãrẹ̀ mu wọn, nwọn, si tuká kiri bi awọn agutan ti ko li oluṣọ.

37 Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni ikorè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan;

38 Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikorè ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikorè rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28