Mat 19 YCE

Ẹ̀kọ́ nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn

1 O si ṣe, nigbati Jesu pari ọ̀rọ wọnyi tan, o kuro ni Galili, o si lọ si ẹkùn Judea li oke odò Jordani.

2 Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, o si mu wọn larada nibẹ̀.

3 Awọn Farisi si wá sọdọ rẹ̀, nwọn ndán a wò, nwọn si wi fun u pe, O ha tọ́ fun ọkunrin ki o kọ̀ aya rẹ̀ silẹ nitori ọ̀ran gbogbo?

4 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo,

5 O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan.

6 Nitorina nwọn ki iṣe meji mọ́ bikoṣe ara kan. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn.

7 Nwọn wi fun u pe, Ẽṣe ti Mose fi aṣẹ fun wa, wipe, ki a fi iwe ikọsilẹ fun u, ki a si kọ̀ ọ silẹ?

8 O wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin ni Mose ṣe jẹ fun nyin lati mã kọ̀ aya nyin silẹ, ṣugbọn lati igba àtetekọṣe wá kò ri bẹ̃.

9 Mo si wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣepe nitori àgbere, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.

10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Bi ọ̀ran ọkunrin ba ri bayi si aya rẹ̀, kò ṣànfani lati gbé iyawo.

11 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Gbogbo enia kò le gbà ọ̀rọ yi, bikoṣe awọn ẹniti a fi bùn.

12 Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a.

Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde

13 Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi.

14 Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun.

15 O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀.

Ìtàn Ọdọmọkunrin Ọlọ́rọ̀

16 Si kiyesi i, ẹnikan tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Olukọni rere, ohun rere kili emi o ṣe, ki emi ki o le ni ìye ainipẹkun?

17 O si wi fun u pe, Eṣe ti iwọ fi pè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun: ṣugbọn bi iwọ ba nfẹ wọ̀ ibi ìye, pa ofin mọ́.

18 O bi i lẽre pe, Ewo? Jesu wipe, Iwọ kò gbọdọ pa enia; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jale; Iwọ kò gbọdọ jẹri eke;

19 Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ.

20 Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù?

21 Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin.

22 Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀.

23 Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun.

24 Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.

25 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là?

26 Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe.

27 Nigbana ni Peteru dahùn, o si wi fun u pe, Wò o, awa ti fi gbogbo rẹ̀ silẹ, awa si ntọ̀ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni?

28 Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila.

29 Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun.

30 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28