1 NI ijọ wọnni ni Johanu Baptisti wá, o nwasu ni ijù Judea,
2 O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.
3 Nitori eyi li ẹniti woli Isaiah sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọ̀na rẹ̀ tọ́.
4 Aṣọ Johanu na si jẹ ti irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ si ẹ̀gbẹ rẹ̀; onjẹ rẹ̀ li ẽṣú ati oyin ìgan.
5 Nigbana li awọn ara Jerusalemu, ati gbogbo Judea, ati gbogbo ẹkùn apa Jordani yiká jade tọ̀ ọ wá,
6 A si mbaptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn.
7 Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ awọn Farisi ati Sadusi wá si baptismu rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀?
8 Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada:
9 Ki ẹ má si ṣe rò ninu ara nyin, wipe, Awa ní Abrahamu ni baba; ki emi wi fun nyin, Ọlọrun le yọ ọmọ jade lati inu okuta wọnyi wá fun Abrahamu.
10 Ati nisisiyi pẹlu, a ti fi ãke le gbòngbo igi na; nitorina gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a o ke e lùlẹ, a o si wọ́ ọ jù sinu iná.
11 Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin.
12 Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, yio si gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, yio si kó alikama rẹ̀ sinu abà, ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.
13 Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani sọdọ Johanu lati baptisi lọdọ rẹ̀.
14 Ṣugbọn Johanu kọ̀ fun u, wipe, Emi li a ba baptisi lọdọ rẹ, iwọ si tọ̀ mi wá?
15 Jesu si dahùn, o wi fun u pe, jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀.
16 Nigbati a si baptisi Jesu tan, o jade lẹsẹkanna lati inu omi wá; si wò o, ọrun ṣí silẹ fun u, o si ri Ẹmí Ọlọrun sọkalẹ bi adaba, o si bà le e:
17 Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.