Mat 11 YCE

1 O si ṣe, nigbati Jesu pari aṣẹ rẹ̀ tan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila, o ti ibẹ̀ rekọja lati ma kọni, ati lati ma wasu ni ilu wọn gbogbo.

Johanu Onítẹ̀bọmi Ranṣẹ sí Jesu

2 Nigbati Johanu gburo iṣẹ Kristi ninu tubu, o rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji,

3 O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran?

4 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹnyin gbọ́, ti ẹ si ri fun Johanu:

5 Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi.

6 Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti kì yio ri ohun ikọsẹ ninu mi.

7 Nigbati nwọn si lọ, Jesu bẹrẹ si sọ fun awọn enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade lọ iwò ni ijù? Ifefe ti afẹfẹ nmì?

8 Ani kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ẹniti nwọ̀ aṣọ fẹlẹfẹlẹ mbẹ li afin ọba.

9 Ani kili ẹnyin jade lọ iṣe? lati lọ iwò wolĩ? Lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù wolĩ lọ.

10 Nitori eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.

11 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si ẹniti o ti idide jù Johanu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ.

12 Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a.

13 Nitori gbogbo awọn wolĩ ati ofin li o wi tẹlẹ ki Johanu ki o to de.

14 Bi ẹnyin o ba gbà a, eyi ni Elijah ti mbọ̀ wá.

15 Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

16 Ṣugbọn kili emi iba fi iran yi wé? O dabi awọn ọmọ kekeke ti njoko li ọjà ti nwọn si nkọ si awọn ẹgbẹ wọn,

17 Ti nwọn si nwipe, Awa fun fère fun nyin ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun.

18 Nitori Johanu wá, kò jẹ, bẹ̃ni kò mu, nwọn si wipe, o li ẹmi èṣu.

19 Ọmọ-enia wá, o njẹ, o si nmu, nwọn wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn a dare fun ọgbọ́n lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ wá.

Ìdájọ́ lórí Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada

20 Nigbana li o bẹ̀rẹ si iba ilu wọnni wi, nibiti o gbé ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ agbara rẹ̀, nitoriti nwọn kò ronupiwada;

21 Egbé ni fun iwọ, Korasini! egbé ni fun iwọ, Betsaida! ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.

22 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Tire pẹlu Sidoni li ọjọ idajọ jù fun ẹnyin lọ.

23 Ati iwọ Kapernaumu, a o ha gbé ọ ga soke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ si Ipo-oku: nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu rẹ ninu Sodomu, on iba wà titi di oni.

24 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu li ọjọ idajọ jù fun iwọ lọ.

Jesu ni Ìtura Àwọn Olùpọ́njú

25 Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́.

26 Gẹgẹ bẹ̃ na ni, Baba, nitori bẹ̀li o tọ́ li oju rẹ.

27 Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun.

28 Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ́, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin.

29 Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin.

30 Nitori àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28