Mat 13 YCE

Òwe Afunrugbin

1 LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun.

2 Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun.

3 O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin;

4 Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.

5 Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ;

6 Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ.

7 Diẹ si bọ́ sãrin ẹ̀gún; nigbati ẹ̀gún si dàgba soke, o fun wọn pa.

8 Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.

9 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́.

Ìdí tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti iwọ fi nfi owe ba wọn sọ̀rọ?

11 O si dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba ọrun, ṣugbọn awọn li a kò fifun.

12 Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a ó fifun, on o si ni li ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti ko ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni.

13 Nitorina ni mo ṣe nfi owe ba wọn sọ̀rọ; nitori ni riri, nwọn kò ri, ati ni gbigbọ, nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni kò yé wọn.

14 Si ara wọn ni ọrọ̀ Isaiah wolí si ti ṣẹ, ti o wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati riri ẹnyin o ri, ẹnyin kì yio si moye.

15 Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada.

16 Ṣugbọn ibukun ni fun oju nyin, nitoriti nwọn ri, ati fun etí nyin, nitoriti nwọn gbọ́.

17 Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ wolĩ ati olododo ni nfẹ ri ohun ti ẹnyin ri, nwọn kò si ri wọn; nwọn si nfẹ gbọ́ ohun ti ẹ gbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn.

Ìtumọ̀ Òwe Afunrugbin

18 Nitorina ẹ gbọ́ owe afunrugbin.

19 Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na.

20 Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan.

21 Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀.

22 Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso.

23 Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.

Òwe Èpò láàrin Ọkà

24 Owe miran li o pa fun wọn, wipe; Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀:

25 Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ.

26 Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu.

27 Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ bãle na tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun u pe, Oluwa, irugbin rere ki iwọ fún sinu oko rẹ? nibo li o ha ti li èpo buburu?

28 O si wi fun wọn pe, Ọtá li o ṣe eyi. Awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si bi i pe, Iwọ ha fẹ́ ki a lọ fà wọn tu kuro?

29 O si wipe, Bẹ̃kọ, nigbati ẹnyin ba ntu èpo kuro, ki ẹnyin ki o má bà tu alikama pẹlu wọn.

30 Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi.

Òwe Wóró Musitadi kan ati Ìwúkàrà

31 Owe miran li o pa fun wọn, wipe, Ijọba ọrun dabi wóro irugbin mustardi kan, eyiti ọkunrin kan mu ti o si gbìn sinu oko rẹ̀:

32 Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀.

33 Owe miran li o pa fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o sin sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ fi di wiwu.

Ìlò Òwe

34 Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu fi powe fun awọn ijọ enia; kò si ba wọn sọ̀rọ bikoṣe li owe:

35 Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá.

Ìtumọ̀ Òwe Èpò ninu Oko Ọkà

36 Nigbana ni Jesu rán ijọ enia lọ, o si wọ̀ ile; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, wipe, Sọ idi owe èpo ti oko fun wa.

37 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li ẹniti nfunrugbin rere;

38 Oko li aiye; irugbin rere li awọn ọmọ ijọba; èpo si li awọn ọmọ ẹni buburu ni;

39 Ọta ti o fún wọn li Èṣu; igbẹhin aiye ni ikorè; awọn angẹli si li awọn olukore.

40 Nitorina gẹgẹ bi a ti kó èpo jọ, ti a si fi iná sun wọn; bẹ̃ni yio ri ni igbẹhin aiye.

41 Ọmọ-enia yio rán awọn angẹli rẹ̀, nwọn o si kó gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ̀ ni ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ.

42 Yio si sọ wọn sinu iná ileru: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà.

43 Nigbana li awọn olododo yio ma ràn bi õrun ni ijọba Baba wọn. Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́.

Òwe Ìṣúra Iyebíye tí Wọ́n Fi Pamọ́

44 Ijọba ọrun si dabi iṣura ti a fi pamọ́ sinu oko, ti ọkunrin kan ri, ti o pa a mọ́; nitori ayọ̀ rẹ̀, o lọ, o si ta gbogbo ohun ti o ni, o si rà oko na.

Òwe Ìlẹ̀kẹ̀

45 Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi ọkunrin oniṣowo kan, ti nwá perli ti o dara:

46 Nigbati o ri perli olowo iyebiye kan, o lọ, o si tà gbogbo nkan ti o ni, o si rà a.

Òwe Àwọ̀n

47 Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi àwọn, ti a sọ sinu okun, ti o si kó onirũru ohun gbogbo.

48 Nigbati o kún, eyi ti nwọn fà soke, nwọn joko, nwọn si kó eyi ti o dara sinu agbọ̀n, ṣugbọn nwọn kó buburu danù.

49 Gẹgẹ bẹ̃ni yio si ri nigbẹhin aiye: awọn angẹli yio jade wá, nwọn o yà awọn enia buburu kuro ninu awọn olõtọ,

50 Nwọn o si sọ wọn sinu iná ileru; nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Nǹkan Titun ati Nǹkan Àtijọ́ ninu Àpò Ìṣúra

51 Jesu bi wọn pe, Gbogbo nkan wọnyi yé nyin bi? Nwọn wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa.

52 O si wi fun wọn pe, Nitorina ni olukuluku akọwe ti a kọ́ sipa ijọba ọrun ṣe dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle, ti o nmu ọtun ati ogbó nkan jade ninu iṣura rẹ̀.

Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu

53 Nigbati o ṣe, ti Jesu pari owe wọnyi tan, o ti ibẹ̀ lọ kuro.

54 Nigbati o si de ilu on tikalarẹ, o kọ́ wọn ninu sinagogu wọn, tobẹ̃ ti ẹnu yà gbogbo wọn, nwọn si wipe, Nibo li ọkunrin yi ti mu ọgbọ́n yi ati iṣẹ agbara wọnyi wá?

55 Ọmọ gbẹnagbẹna kọ yi? iya rẹ̀ kọ́ a npè ni Maria? ati awọn arakunrin rẹ̀ kọ́ Jakọbu, Jose, Simoni, ati Juda?

56 Ati awọn arabinrin rẹ̀, gbogbo wọn ki o mba wa gbé nihinyi? nibo li ọkunrin yi ti mu gbogbo nkan wọnyi wa?

57 Bẹ̃ni nwọn kọsẹ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Kò si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu ati ni ile on tikararẹ̀.

58 On kò si ṣe ọ̀pọ iṣẹ agbara nibẹ̀, nitori aigbagbọ́ wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28