29 Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin.
30 Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan.
31 Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.
32 Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
33 Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
34 Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà.
35 Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀.