34 Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà.
35 Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀.
36 Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ̀.
37 Ẹniti o ba fẹ baba tabi iya jù mi lọ, kò yẹ ni temi: ẹniti o ba si fẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù mi lọ, kò si yẹ ni temi.
38 Ẹniti kò ba si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin, kò yẹ ni temi.
39 Ẹniti o ba ri ẹmi rẹ̀, yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on ni yio si ri i.
40 Ẹniti o ba gbà nyin, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi.