7 Nigbati nwọn si lọ, Jesu bẹrẹ si sọ fun awọn enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade lọ iwò ni ijù? Ifefe ti afẹfẹ nmì?
8 Ani kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ẹniti nwọ̀ aṣọ fẹlẹfẹlẹ mbẹ li afin ọba.
9 Ani kili ẹnyin jade lọ iṣe? lati lọ iwò wolĩ? Lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù wolĩ lọ.
10 Nitori eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.
11 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si ẹniti o ti idide jù Johanu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ.
12 Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a.
13 Nitori gbogbo awọn wolĩ ati ofin li o wi tẹlẹ ki Johanu ki o to de.