20 Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan.
21 Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀.
22 Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso.
23 Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.
24 Owe miran li o pa fun wọn, wipe; Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀:
25 Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ.
26 Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu.