1 LI akokò na ni Herodu tetrarki gbọ́ okikí Jesu,
2 O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀.
3 Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀.
4 Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i.
5 Nigbati o si nfẹ pa a, o bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.