3 Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀.
4 Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i.
5 Nigbati o si nfẹ pa a, o bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.
6 Ṣugbọn nigbati a nṣe iranti ọjọ ibí Herodu, ọmọbinrin Herodia jó lãrin wọn, inu Herodu si dùn.
7 Nitorina li o ṣe fi ibura ṣe ileri lati fun u li ohunkohun ti o ba bère.
8 Ẹniti iya rẹ̀ ti kọ́ tẹlẹ ri, o wipe, Fun mi li ori Johanu Baptisti nihinyi ninu awopọkọ.
9 Inu ọba si bajẹ: ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati awọn ti o bá a joko tì onjẹ, o ni ki a fi fun u.