1 AWỌN Farisi pẹlu awọn Sadusi si wá, nwọn ndán a wò, nwọn si nfẹ ki o fi àmi hàn fun wọn lati ọrun wá.
2 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Nigbati ó ba di aṣalẹ, ẹnyin a wipe, Ọjọ ó dara: nitoriti oju ọrun pọ́n.
3 Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi?
4 Iran buburu ati panṣaga nfẹ àmi; a kì yio si fi àmi fun u, bikoṣe àmi ti Jona wolĩ. O si fi wọn silẹ, o kuro nibẹ.
5 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si de apakeji, nwọn gbagbé lati mu akara lọwọ.
6 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹ si mã sọra niti iwukara awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.
7 Nwọn si mbá ara wọn ṣaroye, wipe, Nitoriti awa ko mu akara lọwọ ni.