12 Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn kò si mọ̀ ọ, ṣugbọn nwọn ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i. Gẹgẹ bẹ̃ na pẹlu li Ọmọ-enia yio jìya pupọ̀ lọdọ wọn.
13 Nigbana li o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li ẹniti o nsọ̀rọ rẹ̀ fun wọn.
14 Nigbati nwọn si de ọdọ ijọ enia, ọkunrin kan si tọ ọ wá, o kunlẹ fun u, o si wipe,
15 Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba pupọ sinu omi.
16 Mo si mu u tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada.
17 Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin.
18 Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna.