24 Nigbati nwọn de Kapernaumu, awọn ti ngbà owodè tọ̀ Peteru wá, wipe, olukọ nyin ki isan owodè?
25 O wipe, Bẹ̃ni. Nigbati o si wọ̀ ile, Jesu ṣiwaju rẹ̀, o bi i pe, Simoni, iwọ ti rò o si? lọwọ tali awọn ọba aiye ima gbà owodè? lọwọ awọn ọmọ wọn, tabi lọwọ awọn alejò?
26 Peteru wi fun u pe, Lọwọ awọn alejò. Jesu wi fun u pe, Njẹ awọn ọmọ bọ́.
27 Ṣugbọn ki a má bã bí wọn ninu, iwọ lọ si okun, ki o si sọ ìwọ si omi, ki o si mu ẹja ti o ba kọ́ fà soke; nigbati iwọ ba si yà a li ẹnu, iwọ o ri ṣekeli kan nibẹ̀: on ni ki o mu, ki o si fifun wọn fun temi ati tirẹ.