1 LAKOKÒ na li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Tali ẹniti o pọ̀ju ni ijọba ọrun?
2 Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn,
3 O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun.
4 Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun.
5 Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi,