9 Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o lọ sinu ìye li olojukan, jù ki o li oju meji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apãdi.
10 Kiyesara ki ẹnyin má gàn ọkan ninu awọn kekeke wọnyi; nitori mo wi fun nyin pe, nigbagbogbo li ọrun li awọn angẹli wọn nwò oju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
11 Nitori Ọmọ-enia wá lati gbà awọn ti o ti nù là.
12 Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi?
13 Njẹ bi o ba si ri i lõtọ ni mo wi fun nyin, o yọ̀ nitori agutan na yi, jù mọkandilọgọrun iyokù lọ ti ko nù.
14 Gẹgẹ bẹ̃ni kì iṣe ifẹ Baba nyin ti mbẹ li ọrun, ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ki o ṣegbé.
15 Pẹlupẹlu bi arakunrin rẹ ba sẹ̀ ọ, lọ sọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ fun u ti iwọ tirẹ̀ meji: bi o ba gbọ́ tirẹ, iwọ mu arakunrin rẹ bọ̀ sipò.