11 Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia.
12 Bi Ọlọrun ti kìlọ fun wọn li oju alá pe, ki nwọn ki o máṣe pada tọ̀ Herodu lọ mọ́, nwọn gbà ọ̀na miran lọ si ilu wọn.
13 Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a.
14 Nigbati o si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀ li oru, o si lọ si Egipti;
15 O si wà nibẹ̀ titi o fi di igba ikú Herodu; ki eyi ti Oluwa wi lati ẹnu woli nì ki o le ṣẹ, pe, Ni Egipti ni mo ti pè ọmọ mi jade wá.
16 Nigbati Herodu ri pe, on di ẹni itanjẹ lọdọ awọn amoye, o binu gidigidi, o si ranṣẹ, o si pa gbogbo awọn ọmọ ti o wà ni Betlehemu ati ni ẹkùn rẹ̀, lati awọn ọmọ ọdún meji jalẹ gẹgẹ bi akokò ti o ti bere lẹsọlẹsọ lọwọ awọn amoye na.
17 Nigbana li eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Jeremiah wa ṣẹ, pe,