5 Nwọn si wi fun u pe, Ni Betlehemu ti Judea ni: nitori bẹ̃li a kọwe rẹ̀ lati ọwọ́ woli nì wá,
6 Iwọ Betlehemu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israeli awọn enia mi.
7 Nigbana ni Herodu pè awọn amoye na si ìkọkọ, o sì bi wọn lẹsọlẹsọ akokò ti irawọ na hàn.
8 O si rán wọn lọ si Betlehemu, o wipe, Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu.
9 Nigbati nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ọba, nwọn lọ; si wò o, irawọ ti nwọn ti ri lati ìha ìla-õrùn wá, o ṣãju wọn, titi o fi wá iduro loke ibiti ọmọ-ọwọ na gbé wà.
10 Nigbati nwọn si ri irawọ na, nwọn yọ̀ ayọ nlanla.
11 Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia.