11 Nigbati nwọn gbà a tan, nwọn nkùn si bãle na,
12 Wipe, Awọn ará ikẹhin wọnyi ṣiṣẹ kìki wakati kan, iwọ si mu wọn bá wa dọgba, awa ti o ti rù ẹrù, ti a si faradà õru ọjọ.
13 O si da ọkan ninu wọn lohùn pe, Ọrẹ́, emi ko ṣìṣe si ọ: iwọ ki o ba mi pinnu rẹ̀ si owo idẹ kan li õjọ?
14 Gbà eyi ti iṣe tirẹ, ki o si ma ba tirẹ lọ: emi o si fifun ikẹhin yi, gẹgẹ bi mo ti fifun ọ.
15 Kò ha tọ́ ki emi ki o fi nkan ti iṣe ti emi ṣe bi o ti wù mi? oju rẹ korò nitoriti emi ṣe ẹni rere?
16 Bẹ̃li awọn ikẹhin yio di ti iwaju, awọn ẹni iwaju yio si di ti ikẹhin: nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn.
17 Jesu si ngoke lọ si Jerusalemu, o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila si apakan li ọ̀na, o si wi fun wọn pe,