25 Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹnyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a ma lò agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba.
26 Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ̀ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin;
27 Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin:
28 Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.
29 Bi nwọn ti nti Jeriko jade, ọ̀pọ enia tọ̀ ọ lẹhin.
30 Si kiyesi i, awọn ọkunrin afọju meji joko leti ọ̀na, nigbati nwọn gbọ́ pe Jesu nrekọja, nwọn kigbe soke, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.
31 Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.