3 O si jade lakokò wakati ẹkẹta ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran, nwọn duro nibi ọja,
4 O si wi fun wọn pe; Ẹ lọ si ọgba ajara pẹlu, ohunkohun ti o ba tọ́ emi o fifun nyin. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ sibẹ̀.
5 O tún jade lọ lakokò wakati kẹfa ati kẹsan ọjọ, o si ṣe bẹ̃.
6 O si jade lọ lakokò wakati kọkanla ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran ti o duro, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe?
7 Nwọn wi fun u pe, Nitoriti kò si ẹni ti o fun wa li agbaṣe; O wi fun wọn pe, Ẹ lọ pẹlu sinu ọgba ajara; eyi ti o ba tọ́ li ẹnyin o ri gbà.
8 Nigbati o di oju alẹ oluwa ọgba ajara wi fun iriju rẹ̀ pe, Pè awọn alagbaṣe nì, ki o si fi owo agbaṣe wọn fun wọn, bẹ̀rẹ lati ẹni ikẹhin lọ si ti iṣaju.
9 Nigbati awọn ti a pè lakokò wakati kọkanla ọjọ de, gbogbo wọn gbà owo idẹ kọkan.