31 Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.
32 Jesu si dẹsẹ duro, o pè wọn, o si wipe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin?
33 Nwọn wi fun u pe, Oluwa, ki oju wa ki o le là.
34 Bẹ̃ni Jesu ṣãnu fun wọn, o si fi ọwọ́ tọ́ wọn li oju: lọgan oju wọn si là, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.