6 Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn.
7 Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a.
8 Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na.
9 Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun.
10 Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi?
11 Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.
12 Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.