16 Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia.
17 Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? o tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́?
18 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe?
19 Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá.
20 O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi?
21 Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
22 Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ.