23 Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i,
24 Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀.
25 Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀:
26 Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje.
27 Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu.
28 Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i.
29 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun.