33 Nigbati awọn enia gbọ́ eyi, ẹnu yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀.
34 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́ pe, o pa awọn Sadusi li ẹnu mọ́, nwọn pè ara wọn jọ.
35 Nigbana li ọkan ninu wọn, ti iṣe amofin, ndán a wò, o si bi i lẽre ọ̀rọ kan, wipe,
36 Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin?
37 Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ.
38 Eyi li ekini ati ofin nla.
39 Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.