38 Eyi li ekini ati ofin nla.
39 Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
40 Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́.
41 Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn,
42 Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni.
43 O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe,
44 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?