40 Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́.
41 Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn,
42 Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni.
43 O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe,
44 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?
45 Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀?
46 Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.