15 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ.
16 Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese.
17 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́?
18 Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese.
19 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́?
20 Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀.
21 Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀.