2 Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ.
3 Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba.
4 O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o.
5 O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso.
6 Awọn olori alufa si mu owo fadaka na, nwọn si wipe, Ko tọ́ ki a fi i sinu iṣura, nitoripe owo ẹ̀jẹ ni.
7 Nwọn si gbìmọ, nwọn si fi rà ilẹ amọ̀koko, lati ma sinkú awọn alejò ninu rẹ̀.
8 Nitorina li a ṣe npè ilẹ na ni Ilẹ ẹ̀jẹ, titi di ọjọ oni.